Translate

Thursday 11 April 2013

NJE O N SIYEMEJI NIPA JESU.


                                                  
      E je kin fi asiko yi  so fun yin pe ipa meji ni eniyan pin si,Okunrin tabi Obinrin, Eniyan kole sai yan okan ninu nkan meji yi, ninu ki o sonu tabi ki a gbaala, eyiti o tumo sipe Esu tabi Olo- run ni oga re,Kini e ro wipe o fa iyapa larin eniyan ati Olorun,eyo oro meta ni ESE {SIN} “1Johanu 3:4 wipe Enikeni ti o ba ndese o uru ofin pelu, nitori ese ni riru ofin” E je ki a tun kaa siwaju  1johanu3:8 Eniti o ba ndese ti Esu ni nitori ni atete kose ni esu ti n dese nito- ri eyini Omo Olorun se farahan ki o le pa ise esu run. je ki otito yi ki o ye o wipe gbogbo eniyan ti a bi nipase Okun rin akoko “Adamu” ati Obinrin akoko “Efa” {nipa ibasepo Okunrin ati Obin- rin elese ni} Awa naa gbodo pa ise-Esu run ninu aye wa, Niwon igbati nko ti ni anfani lati wa lodo yin ni loo-loo yi Ey-in gan ni onidajo arayin nipase Oro Olo run, Jesu wipe nipa eso won la o fi mo won. Bi iwo naa ti mo iyato ti o wa lar- in igi eleso;mango ati ibepe, agbado ati oka-baba.Eyi nse apere boya a so eso to dara tabi buburu ninu aye ti a wa lowo yi. Fun apere gbogbo eniyan lomo pe ko dara lati jale gegebi ofin orileede ti laa kale fun wa,eyiti o tumosi wipe ti a ba ri enikan ti o fe lo jale iru eni bee yio ko gbogbo nkan ija lowo ni lati dabobo ara re fun ise ti o fe se yala ni osan gangan tabi ni oru oganjo,Sugbon ti owo palaba re ba lo segi{if he\she is caught}  ti owo awon agbofinro ba lo te tabi O.P.C .tabi awon ajo miran tiwon ngbo gun ti iwa ibaje lawujo, atimo wipe iru eni bee ko le lo lai jiya fun iru ese ti o ba da labe ofin, bee ni BIBELI so gbogbo nkan ti o je ese fun wa lai fepo-boyo rara. Je kin so fun yin pe ti e ba ntesiwa ju pelu iwa buburu bayi Esu gan ni oludari iru eniyan bee “Eyin ko mo pe awon alaisoto ki yio jogun ijoba Olorun ? ki a ma tan yin je, ki ise awon agbere, aborisa,awon pansaga, awon olojukoko ro, awon omuti, awon elegan, awon aloni-lowo-gba ni yio jogun ijoba Olorun 1Korinti 6:9-10”. Ti o ba nse okan ninu gbogbo nkan wonyi tabi eyi ti o n se ti emi inu re n ta ko o{eri-okan} Ore mi tooto ki lo de ti o se fi ese sile tabi ki o kunle lori eekun re ki o jewo iru ese bee, ki o si koo sile,nipase oruko kan soso ti a le fi gba eniyan la{JESU} “Sugbon bi awa ba nrin ninu imole, bi o n ti mbe ninu imo- le, awa ni idapo pelu ara wa, eje Jesu Kristi omo re ni nwe wa nu kuro ninu ese gbogbo 1Johanu1:7 ”. “Pe, bi iwo ba fi enu re jewo Jesu loluwa, ti iwo si gbagbo lokan re pe Olorun jii dide kuro ninu oku a o gba o la Romu 10:9” “Sugbon lai si igbagbo ko see se lati wu, nitori eniti o ba nto Olorun wa ko le sai gbagbo pe o onu be, ati pe onu ni olusesan fun awon ti o fi arabale waa,iwe Heberu 11:6”.Kin se awon to ti tori owo wa Olorun, Kin se awon to ti tori Omo waa tabi kin se awon to ti tori Ile wa Olorun, tabi tori Ile wa  Olorun {Land], tabi awon to ti tori Onje wa Olorun,tabi tori Moto wa Olorun,tabi nkan aye yi ti yio dibaje lojo kan ti won tori re wa Olorun, Sugbon awon to ti tori igbala -okan won wa Olorun. Awon wonyi ni bibeli sope awon ti o fi ara ba le waa. Nigbti o ba se eyi ni Olorun yio wa fun  o ni idasile kuro lowo agbara okunkun, leyin eyi iwo naa a le seso rere. “ Nitori na bi enikeni ba wa ninu Jesu o ti di eda titun, ohun atijo ti koja lo {iwa ole, ija, agbere, pansaga, iro-pipa,ikorira..}  Ni tooto ohun gbogbo yio dotun”2 Korinti   5:17.”  “Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mo  pe omo-ehin ni enyin ise, nigbati  enyin ba ni ife si  omonikeji nyin, Johanu 13:35”. Je  kin so fun yin nipa  sise awon nkan wonyi  lati maa ka Bibeli re,lati maa gbo ORO- OLORUN ti o ye koro, ati lati ma paa- mo, Ki o si ma  lepa ati se awari Otito kan funrare tabi ju bee lo ninu Bibeli re,Iwo na  ti deda- tuntun {ATUNBI} niyen jowo gbadura yi pelu mi “Jesu Oluwa mo pe o sinu okan mi, mo si fe ki o ma bami gbe titi, gege bi Oro Olo- run ti wipe, ti enikan ba gbohun re ti o silekun okan re sile Emi(JESU) yio wole, Emi yio si ma ba jeun.‘biko se pe e ba ronupinwada e o segbe bee gege’, Oluwa, kin maa ba segbe, Oluwa gba mi la-gba-tan kin ba le joba pelu re ni- keyin, ni oruko Jesu Oluwa wa,AMIN.  Nipari, Oluwa fun mi ni ogbon ati oye lati maa se ife tire nikan laelae, mase gba Esu laye lati da mi pada sinu awon ese ti mo ti jewo ti mo si ti ko sile titi aye mi {AMIN}.
   Fun alaye sii, Ibere, Amoran, Ebe adura,Eri Yin, tabi E n fe iwe yi sii  kowe si :-
Pastor J.A.Adewumi Configay.
ReviveThe Whole World For Christ.   
P.O.Box 1736,
Osogbo, Osun State. Nigeria.   





TI OLORUN BA FI SI O LO KAN LATI RAN ILE-ISE IWE YI LOWO SEE LONI OLA LEE PE JU,  KOSI  IYE OWO TI O KERE JU LATI FI SILE TABI TI O POJU, KI ORO OLORUN LE MAA GBINLE SII.                                             




No comments:

Post a Comment