Translate

Thursday 11 April 2013

“Nitoriti nwon a ma wi, Sugbon won kiise”.

  

    
“Sugbon e ma se gege bi ise won: nitori nwon a ma wi sugbon nwon kiise”Mathew 23:3.Iru awon eniyan bayi po ninu ijo loni eyi gan ni a npe ni “Agabagebe”,nitori idi eyi gbogbo eko ati awon oro Olorun tiwo- n ngbo koni-tumo si won rara. Won pe ara won ni Juu{Jews}nitooto won je Sinago- gu Esu, niti eko won mo nipa re daradara, Sugbon won kuna lati le fi eko ti won nko si ise. Akoko niyi o lati ni emi bii ti Woli Esra ninu aye wa, paapaa julo ninu ijo wa “Nitori Esra ti mura tan li okan re lati ma wa ofin Oluwa, ati lati see,ati lati ma koni li ofin ati idajo ni Isreali”Esra 7:10. Mo fe ki egbe otito yi yewo gegebi olori,oludari,   olusoaguntan,omoleyin,oludasile ati awon alafenu je Kristeni. Ki o yipada ninu iwa buburu re, e je ki a je apere rere fun awon ti a n ko ni oro Olorun, ka si tun je ki oro wa ati eko wa wa ni ibamu pelu Bibeli. Bibeli wipe “Ninu ohun gbogbo e fi ara yin han gegebi apere rere, ninu eko fi ara re han bi alaidibaje”Aposteli Paulu lo n gba Titu niyanju.Paulu ti gbo nipa awon eleko-eke, o tun so fun Titu pe o gbodo gbiyanju lati ko eko ti o ye koro ati awon eko ti o wa ni ibamu pelu oro Olorun yato si ogbon ori eniyan, ki awon agba okun- rin je eni iwontunwosi, eni-owo,alairekoja, eniti o ye kooro nigbagbo, ni ife, ni suru. Bee gege ni ki awon agba obinrin je enio-wo ni iwa, ki nwon ma je asoro-eni-lehin tabi omuti, bikose olukoni ni ohun rere, ki won ki o le to awon odomobinrin lati feran awon oko won, lati feran awon omo won, lati je alairekoja, mimo, osise nile, eni rere, awon ti nteriba fun awon oko won, ki oro Olorun ki o mase di isoro-odi si, ninu ohun gbogbo maa fi ara re han li apere ise rere, ninu eko maa fi aisebaje han, iwa agba,Titu 2:1-8; loni awon alafenu je Kristeni po ninu aye, “Jesu wi fun ijo enia ati awon omoehin  re pe, awon akowe pelu awon Farisi joko ni ipo Mose! Nitorina  ohunkohun  gbogbo ti won ba wipe ki e kiyesi, e maa kiyesi  won
 ki e si maa se won, sugbon e maa se gegebi ise won: nitoriti nwon a ma wi, sugbon nwon ki ise. Nitori nwon a di eru wuwo ti o si soro lati ru, nwon a si gbee ka awon enia li ejika, sugbon awon tikarawon ko je fi ika won kan eru naa, Mathew 23:1 - 4. Loni awon  eniyan ma nfe ipo giga lawujo, igba- gbo tiwon ni ti ipo giga, tabi  ohunkohun ti  o ba ma na won lati gbaa tabi raa pa patapa ta, tabi bi oba la emi lo won yio pa eniyan bee lona ati de iru ipo. Sugbon gbogbo ise won ni won ma nse tori ki eniyan le ri won.. won nfe ipo ola nibi ase, ati ibujoko ola ni Sinagogu, ati ikini li oja ati ki enia maa pe won pe Rabbi,Rabbi,{oluko} pelu gbogbo nkan wonyi Olorun nfe iwa irele, E ma si se pe enikan ni Baba nyin li aye, nitori enikan ni Baba eniti mbe li orun. Ki a ma si se pe yin ni Olukoni nitori okan li Olu- koni yin, ani Kristi. Sugbon eniti o ba poju ninu nyin, On ni yio je iranse nyin, Enikeni ti o ba si gbe ara re ga li a o re sile, Enikeni ti o ba re ara re sile li a o gbe ga.{ese 8-12} Nitori eyi Olorun binu si igbe aye agabage- be “Egbe ni fun nyin, eyin akowe ati Farisi, agabagebe: nitori enyin je ile awon opo run ati nitori asehan, e ngbadura gigun: nitoriti enyin tikarayin ko wole beli enyin ko je ki awon ti nwole ki o wole. Je kin so fun yin pelu idaniloju pe awon eniyan wonyi je okuta idigbolu fun elomiran , paapaa julo awon ti o fe gba Ihinrere ti Jesu gbo.Won tile tun mo nipa eko daradara ti won ko ni telee, eyi lo fa ti Jesu se fi won bu{curse} “Egbe ni fun nyin eyin amona afoju, ti o n wipe Enikeni ti o ba fi Tempili bura, kosi nkan, Sugbon Enikeni ti o ba fi Wura, tabi Tempili ti nso Wura di mimo? ese13- 24; Nje eyin ti  e  wa  ninu Egbe Oni-mo-tara-enikan? , “Egbe ni fun nyin, enyin akowe ati Farisi, agabagebe: nitori enyin nfo  ode ago ati awopoko mo, sugbon inu won kun fun ireje ati wobia. Iwo afoju Farisi, teeko fo eyi ti mbe ninu ago ati awopoko mo na, ki ode  won ki o le mo pelu.Egbe ni fun yin, enyin akowe ati Farisi, agabagebe: nitoriti enyin dabi iboji funfun, ti o dara li ode, sugbon ninu nwon kun fun egungun oku, ati fun egbin gbogbo. Gege bee li enyin pelu farahan li ode bi olododo fun enia, sugbon ninu, e kun fun agabagebe ati ese , ese 25- 33”. Eko dara- dara o dara nitooto, sugbon  eko ti ko ba wa ni ibamu pelu oro Olorun o le yori si iyapa  larin  eniyan  ati  Olorun tabi  iku ayeraye,Sugb- on EMI OLORUN ni nfun ni  IYE lopolo- po, nitori idi eyi fi ara re sile fun Olorun {jowo ara re fun Olorun}ati fun EMI re lati  maa dari igbe aye re lati se IFE Re. Mase dake nitori ailera re tabi eru aikun- oju-osuwon lati wasu, gbiyanju lati maa ka Oro Olorun{Bibeli} tabi ki o se gegebi ase re si O .Soo ki o si see, Olorun Alafia yio wa pelu yin bi e ti nka iwe yi.
  Ni ipari ohunkohun ti ise ooto,ohunkohun ti ise owo,ohunkohun ti se tito, ohunkohun ti o ni irohin rere: bi iwa tito kan ba wa,.... E maa gba nkan wonyi ro.... E maa se won; Olorun alafia yio wa pelu yin, {AMIN}.
Fun alaye sii, ibere, amoran,ebe adura, Eri Yin, tabi e n fe iwe yi  sii,  kowe si :-

ReviveThe Whole World For Christ.   
P.O.Box 1736,
Osogbo, Osun State. Nigeria. 


TI OLORUN BA FI SI O LO KAN LATI RAN ILE-ISE IWE YI LOWO SEE LONI OLA LEE PE JU,  KOSI  IYE OWO TI O KERE JU LATI FI SILE TABI TI O POJU, KI ORO OLORUN LE MAA GBINLE SII.                                             





No comments:

Post a Comment