Translate

Thursday 11 April 2013

EWU FIFI ASIKO DOLA (PROCRASTNATION).

           
 “Loti si jade, o si so fun awon ana re okunrin, ti nwon gbe awon omobirin re ni iyawo, o wipe, e dide, e jade kuro nihinyi; nitori Oluwa yio run ilu yi. Sugbon o dabi eletan loju awon ana re. Nigbati oye si nla, nigbana li awon angeli na le loti ni ire wipe,dide, mu aya re, ati awon omo- birin re mejeji ti owa nihin; ki iwo kio ma barun ninu ese ilu yi. Nigbati o si  nlora, awon okunrin na nawo muu li owo, ati owo aya re ati owoomo birin re mejeji; Oluwa sa sanu fun u ! nwon si mu u jade, nwon si fii sehin odi ilu na”. (Genesis 19:14 -16).“Nigbati o si nlora.....”v 16; Ti a ko ba ni fepo boyo, o gbo oro Olorun nipase an- geli Olorun pe idajo Olorun nbo ati pe a o pa  awon ilu yi run (Sodomu ati Gomorah). Ki se pe Loti gbo oro wonyi nikan, Otun gbaagbo, O tun so fun elomiran. O wa so fun awon ana re pe “ E dide, E jade kuro nihinyi, nitoriti Oluwa yio run ilu yi”. Sugbon ohun ti o bani lokanje ni wipe, lehin ti Loti ti gbo gbogbo nkan wonyi pe idajo nbo lori ilu wonni ti o si tun n lora. Ti o ba je wi pe o seese ki a pe eniyan jade ninu Orun Apadi (Hell) ki won maa bi enikokan pe, ngbo? ki lode ti iwo fi wa lorun apadi tabi iwo ko mo ona-igba -la ni? Mo mo daju pe opolopo ni yio so pe nko ni anfani ati mo ona igbala ni. Sugbon opolopo ni yio so pe, beeni mo mo nipa ona igbala , nko ya si ni. Nje o ni lokan lati lo si Orun Rere bi? Beeni,  mofe lo si Orun Rere; Nitoripe won ti so fun mi tele pe Olorun yio won (weight)ise bubu- ru ti mo ti se, yio si tun won ise rere ti mo ti se, sugbon ti ise rere ba poju buburu lo Yio ju mi si Orun Rere, nitoripe ki se pataki lati gba Jesu loluwa ati Olugbala mi.  Je kin so fun o eko eke leleyi je o!Mase tele iru eko odi bee. Elomiran yio wipe laipe emi naa yio gba  Jesu loluwa ati Olugbala mi. Sugbon je kin so fun o fifi asi- ko dola o lewu pupo. Mo mo daju wipe gbogbo awon  ti won wa lorun Apadi ko niwon yan lati lo sibe, sugbon opolopo loje wipe O gbo nipa Jesu Kristi, sugbon ti o gba wipe asiko ko i ti to ti ohun maa faye ohun fun un, sugbon lojiji ijamba kan sele yala ninu oko (motor) tabi ni ibomiran ti iku de lojiji ti ko sisi  aye lati ronu- piwada tabi jewo ese ti o ti se, ni ireti lati yipa- da patapata tabi lati di omo Olorun ki o le ma reti ijoba Olorun fun okan re.Mofe ki awon eni- yan mo daju pe Bibeli wa, atipe Bibeli yi gan ni oro Olorun, ki awon  eniyan mope Orun Apadi (HELL) wa nitooto ati pe Orun Rere naa wa nitooto gege bi iwe mimo Bibeli ti so fun wa. Gbogbo eniyan ti o ba ku lai ni Olugbala [Jesu Kristi] ninu aye won, won yio yoju si Orun  Apadi.  Awon ti won  jewo  Jesu  loluwa won ki iku to de, won yio lo si Orun Rere. Bibeli je kio di mimo fun wa pe awon tio wa laye a o pa won larada,1Cor.15:51-58. Mofe ki o mo pe Olorun feran re,O si ti la ona abayoo fun o, lati ni igba- la, Olorun fe ki gbogbo eniyan di eni igbala, sugbon je ki nfi otito yi kun wipe, ti gbogbo eniyan ba ko lati gba ihinrere tabi ko Olorun sile, eleyi ko le yi Olorun pada ni ipo re, ki o O sope Ohun ko je Olorun mo.Curtis Hut son wipe “je ki a so fun gbogbo eniyan pe won gbodo ni igbala, sugbon won fe igbala kise low- olowo yi, ki won duro die si”. Je ki nso fun o pe lowolowo ti o nka iwe mi yi ni o gbodo wa Olu- gbala la wa ri ninu okan re tabi ki o to eniyan Olorun lo fun eko si lati gba Jesu loluwa ati Olu gbala re.R.A. Torrey wipe “Ologbon eniyan ni gbati o ba ri nkan ti o ye kio se ki o tete see ki o tete see lesekese,Sugbon omugo eniyan nigbati o ba ri nkan ti o ye ki o se,  yio so pe O dara nitooto lati se,Sugbon nko ni se bayi, ma duro die si. Ta lo le so nkan ti o maa sele ni iseju kan  si asiko yi, ju gbogbo re lo, ko si iru iku ti ko le pa eniyan yala iku Afowororiku, iku ijamba oko ofurufu tabi ti ile, tabi iku jijonamole ati beebee lo {e.t.c} Sugbon gba Jesu loluwa re ki iku to de ba o tabi igbasoke. “Nigbati O nlora..... ..” Kin se ewu sise okan le nikan ni o wa, Ewu ki eniyan padanu emi re na wa o, eniyan je alaye okan, Jesu wipe “Nitoripe ere kini fun eniyan,bi o jere gbogbo aye, ti o si so emi re nu”{marku 8:36} Ti o ba jere gbogbo aye ti o je eniti oni gbogbo nkan aye yi {moto,owo, ile,ile(land, house)omo} Ti o ba wa padanu emi re, iwo gan ni alaga iya tosi [idiotic  bargain]. Eniyan ni Ori-rere,Sugbon esu ati awon omo ogun re lo so ti elomiran di Ori-buruku, Ori-rere yi ni a maa n gbe kiri elomiran yio gbe tire loju sodo[drop it at river side],elomiran yio ju tire sinu afefe, elomiran yio gbe tire fun oko,iyawo tabi omo re. Je kin so otito yi fun yin pe enikan ti o ba n fi igbala okan re sere ni oga awon Omugo, tabi ki eniyan maa so pe ko si aye fun Jesu ninu okan re lojojumo. Kin se ewu ki eniyan padanu emi re nikan ni o wa, Ewu ki eniyan lo si Orun apadi naa wa o,boya iwo ko tile ka si ewu rara, ki eniyan fi nkan ti o dara sile ki o si lo mu eyi ti ko dara. Je kin se apere kan fun yin, eniti o ni Emi-mimo ninu re ti o yan eniti koni lore kori- kosun, O n fi ara re sere niyen ! Je kin so bayi pe Ebun-Emimimo tabi Eso-emi dabi boolu felele[ball] ti eniyan lo n gba nibi ti iso yi kaka- kiri[nails] se e mo pe o ye kio o ronu ara re jinle ki o to maa gba iru boolu yi, tori wipe ti o ba sesi gun iso yio jo ni, wayio yio tun maa gbiyan ju lati fee pada bi o ti wa tele ri. Mo roo kio mase dara re po pelu egbe-okuku niwon igbati o ba jewo JESU loluwa re, dipo eyi, o ye ki o ba won wi ni[iwe Efesu 5:11]. Se e ko gbagbe pe Ewu nla ni ki eniyan lo si Orun-Apaadi, Eyin le ma fe gbo eyi, sugbon o ti di dandan lati soo fun yin. Orun apadi daju O !, eyi ti a n pe ni ina-ajo-iku[burning-hell]niwon igbati eniyan ba ku lai ni JESU,otito ni eyi pe orun apadi n duro dee, se iwo fee lo sibe ni tire?.Okunrin Oloro nii ku asi sin ati ni orun apadi O gboju re soke ninu opo-lopo iya [luku 16:22-23]. Je kin so fun yin Orun apadi je ibi ijiya-ayeraye,o je ibi ainireti rara, o je ibiti a kin dagbere fun Baba, Iya, Egbon, Aburo ati Ore pe odigbose. Orun Apadi je ibiti ko si ona-abayo. Nitorina Agbodo gbiyanju lati yera fun orun-apadi, kin se ibi ti o ye ki iwo ati emi lo. Je kin tun se apere miran fun wa, ka gba wipe nibiti a wa bayi Ki enikan wa so fun wa pe bombu wa ni be {bomb}ti o si ti setan ati bu jade nigbakugba si asiko ti a wa yi. E je kin bere pe,Tani ninu wa ti yio duro ki o bu loju wa?tabi tani yio duro lati se ohun kan tabi omiran ti ko ni wa ona abayo lati sa asala fun emi re?. Eyi nso fun wa nipa ipadabo Jesu leekeji, o je ewu nla fun awon ti ko gbaagbo.O tun je AYO fun awon ti o wa ninu re, mo roo ki o gba JESU yi loni, ki o ye fi asiko re dola. Fi ara re han JESU nipa jijewo ese re lai fikan pamo nibe fun OLUGBALA re, gbogbo ese ti o ti jewo yen ki o koo sile patapata, ki o pee sinu Okan re {JESU},  ki o gbaa tokantokan sinu aye re , ki o si tun setan lati le maa lo si ile ijosin ti o ba sunmo ile re tabi ibi ti won tin soro OLORUN ti o ye kooro “Nitori  o wipe emi ti gbohun re li akoko itewogba,ati li ojo igbala ni mo si ti ran o lowo: kiyesii, nisisiyi ni akoko itewogba; kiyesii, nisisiyi ni ojo igbala” 2Korinti 6:2. Oni yi gan ni akoko igbala tire mase fi asiko dola mo. Mo eyi daju pe ti iku ba lo ka o mo kosi aye ironupiwada leyin iku,fi ti okunrin Oloro ni ati ti Lasaru se Odinwon aye re. Sugbon ranti pe OLA LE PE JU FUN O o.
Fun alaye sii, ibere,amoran,ebe adura, Eri Yin,tabi e n fe iwe yi  sii  kowe si :-

ReviveThe Whole World For Christ.   
P.O.Box 1736,
Osogbo, Osun State. Nigeria.
 GSM :08038352637 ;08060885544.





TI OLORUN BA FI SI O LO KAN LATI RAN ILE-ISE IWE YI LOWO SEE LONI OLA LEE PE JU,  KOSI  IYE OWO TI O KERE JU LATI FI SILE TABI TI O POJU, KI ORO OLORUN LE MAA GBINLE SII.                                             

No comments:

Post a Comment