Translate

Thursday 11 April 2013

EGUN KIN WA LAINIDI.


Kini a n pe ni egun? Bawo ni egun se n wonu aye eniyan?ati pe ona melo ni egun gba nwonu aye eniyan?.  Egun maa nwonu aye  eniyan nipa Aikiyesara, die ree ninu ona ti egun ngba wonu aye eniyan :- (i) Egun lati odo Olorun sori eniyan.(ii)Egun lati odo awon Obi si awon  omo. (iii) Egun lati odo iranse Olorun si  Omo ijo re. (iv) Egun ajogun ba ninu idile ti a ti bi wa. (v) Egun lati odo ore, oko tabi iyawo.Iwe Atumo Ede Pe Egun Ni :- ipe lati ran emi Esu tabi ibi sori eniyan tabi nkan miran ati bebe lo{e.t.c}.Egun maa nso eniyan di alaimose loju elegbe re tabi loju awon tin reti ki o mu nkan bo wa fun won ti eni naa ko si le se bee . Bibeli so pe .....Tani oni ogbe lainidi.... ‘‘iwe owe23 :29’’.Idi kan pataki gbodo wa fun egun ti o wa ninu aye eniyan, yala  ki o je pe won fi se itore anu fun tabi ki o je ti idile ti won,  tabi eyi ti a fi owo ara wa fa fun ara wa {egun afowofa}. je kin sare ran yin leti  fimu{film}  Ogun -Atile wa eyi ti awon Mount Zion  se,  fun gbogbo eniyan ki a le maa fi se odiwon igbe aye wa , lati mo iru ogun ti o n laa  koja yala latile wa ni tabi ajogunba,se bi eranti eniti oga agba ilese pe ki o je oga agba ti eka tilu oyinbo,se bi eranti pe bo se de ibe tan loti so pe ohun o fe gbo nipa esin ti Kristi bi o ti wu ki o mo, eyi losokunfa bi o se da Oludari eto isin won duro {FELLOWSHIP   LEADER} lenu ise oojo re, ti o si je pe ogun atilewa lo n ja , ipo ti ohun bo si lohun yen enikan lo wona ati debe sugbon ti ori tire takoo, se e ko gba- gbe pe o ya were gbeyin ni,Oruko ti o sope ohun ko fe gbo, lo tun pada wa woo san, leyin ti enikan ti o wa nipa ti Olorun tu asiri ogun naa lo je ki o rorun lati tete se itusile fun ninu ogun naa, leyin eyi lo sese wa se alakoso  daadaa, atipe obinrin ojo yen ti won daduro wa bere ise re pada leye -o-soka, ibi ti a maa nfojusi nigba miran ona kin sa ba maa n gbabe lo, E mo eyi  daju pe E le se eniyan dudu loore ki o je wipe eniyan pupa ni Olorun yio so fun pe ki o lo san ore naa tabi kio je eniyan alawofun fun, Sugbon loni eniyan ti a ba se loore ni a o maa reti ki o san fun wa pada, mo fe ki e mo daju pe ko sebun ofe lodo Esu, ti Esu  ba fun o ni ebun kan  yio fe gba mewa dipo re tabi ogun. nigbati o ba gba  mewa  dipo eyo  kan iwo yio tun fi tayo-tayo dupe lowo re pe o see pupo. E je ki a tun pada si die ninu awon ona ti egun ngba wonu aye eniyan. (1) Egun lati  odo  Olorun, Deuteronomy 27:15;  Bibeli  wipe “Egun ni fun Okunrin naa ti o ya ere gbigbe tabi dida, irira si Oluwa,ise owo onisona,tio si gbe e kale ni ikoko, gbogbo eniyan yio si dahun wipe Amin” Leyin eyi Olorun tun fi ejo ti o tan  awon eniyan je ninu ogba Edeni bu “Olorun si wi fun ejo naa pe, nitori ti iwo ti se eyi, a fi o bu ninu gbogbo eran ati ninu gbogbo eranko igbe, inu re ni iwo o fi ma wo,  erupe ile ni iwo o maa je li ojo aye re gbogbo Genesis3:4”. E gbo eyi ti Olorun so fun Kaini ti o pa arakunrin re{Abeli} “Nje nisisiyi a o fi o re lori ile, ti o yanu re gba eje arakunrin re lowo re”Genesis4:11. (2)Egun lati odo Obi si Omo, E je katun se agbeyewo eleyi ninu Bib- eli,Deut 27:16-26. “Egun ni fun eniti ko fi ba- ba re tabi iya re pe,gbogbo eniyan yio si dah- un  wipe Amin.... ”.  Noa gan fi omo re sepe nitori pe o ri ihoho re ti ko si le daso-boo o si wipe“Egbe ni fun Kenaani  iranse ni yio ma se fun awon arakunrin re” Gen 9:25. (3)Egun lati odo iranse  Olorun, E je katun yiri koko yi wo, Olorun maa n gbenu awon iranse re soro tabi lati enu eniyan re tabi ohunkohun ti Olorun ba  fe lo “Josua si gegun li akoko naa wipe egun ni fun okunrin naa niwaju Oluwa ti yio dide, ti yio siko ilu Jeriko yi: pelu iku abi- keyin re ni yio fi gbe ilekun ibode re ro”Josua 6: 26. ninu iwe awon Oba kini1 6:34, ni oro   yi ti se “Hieli ara Beteli ni o pe oro Olorun ni eke, eyiti o mu ki o ko Jeriko bi o se bere re ni akobi re Abiramu ku, nigbati o gbe ilekun re ro ni abikeyin re Segubu ku gegebi oro Oluwa ti o ti ipa Josua omo Nuni so”.(4) Egun idile, egun eyi tun je ogun ti o saba maa n ja eniyan  gan, o maa nso eniyan di alaimose, alainilari, alabuku  larin egbe tabi ogba. Idile miran Egun ti won ni were, ajogun ba tiwon niyen, osi  ni telomiran, aikintojo ni telomiran, aisan oniruru nitelomiran, aikingbe nkan rere se nitelomiran,ati beebee lo, iru egun wo lo nja o tabi iru ogun wo lo n la koja bayi, boya airomo bi ni ogun ti o n la koja, ainise lowo, airalanu, ijakule lenu ise ni telomiran, bayi mo fe ki o pe Jesu sinu aye re ki o ba o dasi isoro naa tabi ki o ba o ba egun naa je patapata . Se e ko gbagbe pe Jesu ba iji wi lojo wonni ninu oko oju omi{Mathew 8:26}. Boya awon isoro wonyi tile je ki oro aye re su O tabi  O tile ti re o ninu Emi  lati je ki o tesiwaju. Mo gbaladura pe Olorun mi yio pase itura sinu aye re, idakeroro yio si ba gbogbo ogun tabi egun naa ti o n ja o loruko Jesu{AMIN}. Bibeli tile so fun wa nipa ona meji ti o wa , ona gboo-ro[Esu] ati ona too-ro[JESU], se e  ko gbagbe pe ona gbooro lo lo sibi iparun ayeraye,ona tooro lo lo sibi iye ayeraye. Bayi ronu ara re eyi ti o fe mu ninu ona mejeji, Sugbon mo ro o ki o yan ona ti Jesu ki o baa le ni isinmi ayeraye leyin ohun gbo- gbo, mo gbaa ladura lekan sii pe, Olorun yio gbawa kuro lowo ise okunkun gbogbo [Amin].                      Fun alaye sii, Ibere, Amoran, Ebe adura, Eri Yin tabi E n fe iwe yi sii, kowe si :-

ReviveThe Whole World For Christ.   
P.O.Box 1736,
Osogbo, Osun State. Nigeria.   

1 comment:

  1. Pasito ejowo egba adura fun mi Lori oro egun idile yi oo.

    ReplyDelete