THIS TRACT MINISTRY IS A WORD OF GOD THAT SHARING TO EVERYBODY TO BE READ AND HAVE LIFE CHANGING i.e FROM BAD LIFE TO GOOD LIFE
Translate
Thursday, 11 April 2013
RU EBUN OLORUN NINU RE SOKE.
“Nitori idi eyi ni mo se nran o leti pe ki iwo ki o maa ru ebun Olorun soke eyiti mbe ninu re nipa gbigbe owo mi le o. Nitoripe Olorun ko fun wa ni emi iberu: bikose ti agbara,ati ti ife,ati ti inu ti o ye koro.Nitorina mase tiju eri Oluwa wa, tabi emi onde re: sugbon ki iwo ki o se alabapin ninu iponju ihinrere gege bi agbara Olorun; Eniti o gbawa la, ti o si fi ipe mimo pe wa, ki ise gege bi ise wa, sugbon gege bi ipinnu ati ore-ofe tire, ti a fifun wa ninu Kristi Jesu lati ayeraye. Sugbon ti a fihan nisisiyi nipa ifarahan Jesu Kristi Olugbala wa, eniti o pa iku re, ti o si mu iye ati aidibaje wa si imole nipase ihinrere,fun eyiti a yan mi se oniwasu ati aposteli ati oluko. Nitori idi eyiti emi se njiya wonyi pelu: sugbon oju ko ti mi: nitori emi mo eniti emi gbagbo, o si da mi loju pe, on le pa ohun ti mo fi lee lowo mo titi di ojo ni. Di apere awon oro ti o ye koro ti iwo ti gbo lodo mi mu, ninu igbagbo ati ife ti mbe ninu Kristi Jesu” 2Timoteu 1:6-13; Mo se atenumo ese kefa “Nitori idi eyi ni mo se nran o leti pe ki iwo ki o maa ru ebun Olorun soke eyiti mbe ninu re nipa gbigbe owo mi le o” Paulu{Paul} kowe yi si arakunrin re Timoteu, o so pe Timoteu ti a ti gbala, Iwo ti o ti ni Emimimo Olorun ti o ngbe ninu re, ti Olorun tun pe lati je okan lara awon iranse re, ti mo si ni anfani lati fi owo mi le o lori gege bi iwon igbagbo ti mo ni lati odo Olorun nitori idi eyi, timoteu ru ebun Olorun soke ninu re ki o si se ohun ti Olorun nbere lowo re. Awon mejeji gbagbo ninu oro Olorun, won gbagbo ninu Olorun kan naa, awon mejeji ni o ti ni igbala okan, ati ipe Olorun ninu aye won, Paulu wa n gbaniyanju lati ru ebun Olorun soke ninu aye re, ninu iwe kini ati ekeji Timoteu, Paulu n tesiwaju lati gba arakunrin re niyanju lati farada inira gege bi omo ogun Kristi, ki o si tun gbiyanju lati fara re se apere iranse Olorun Alaye, ohun ti Paulu se yi lo ye ki gbogbo
wa naa se, nigbati a ko ba ru ebun elomiran soke, ninu eyi gbogbo wa lo fee kuna {fail}, Adupe pe awon die n sa gbogbo ipa ti Olorun fun won lati ru ebun elomiran soke, niwon igbati a ba nwasu ni gbogbo igba ti a ko ri enikan tabi opolopo eniyan lati dide ki won se nkan ti Olorun bere lowo won, mo eyi daju pe a ko i ti sise kankan. Paulu nse eyi lorekore lati le je ki enikan tabi opolopo eniyan gbo ihinrere nipase re, ati lati je ki won se nkan ti Olorun bere lowo won. Paulu, ninu igbiyaju re gan lo mu ki o kowe si awon ijo kan{Romu,Korinti,Fillipi ati bee bee lo}. Se e kuku mo pe awa eniyan a kii fe nkan ti o le ru igbagbo wa soke. Eyi ti yio te opolopo eniyan lorun ju ni ki a maa gbo itan asan ninu ile ijosin bi{alo ijapa,itan ilu oyinbo, ki elomiran bere itan re ni America ki o pari re si Toronto}tabi itan ojo ti won da ijo sile, itan ojo ti o ti wa ninu ijo,{ti ko si idagbasoke kankan ninu aye nipa temi ati tara}.Awon eniyan tile ma n fe ni gbogbo igba ki a sa maa fi oro Olorun boo lai tile nani ati fi oro Olorun bo elomiran. Ki o ko won tan ki won lo jeun lai tile nani lati yewo funrawon lati se awari otito miran funrawon, lati se nkan ti Olorun nfe a gbodo ru ebun Olorun soke ninu aye wa, Mose gan ni iru emi yi lokan re nigbati o so pe “Eyin eniyan e sora e mase gbagbe Olorun” Deuteronomy 6:12. O gbiyanju lati ru ebun Olorun ti o wa laye won soke. Awa naa gbodo mura lati ru ebun tiwa ati telomiran naa soke, boya a fe tabi a ko fe,awon ojogbon ninu imo naa gbodo setan lati ru ebun Olorun soke ninu aye tiwon bakan na. Nje e je mo wipe awon nkan ti o ye ki o maa ru ebun wa soke ti n sele lowolowo bayi, paapaa julo awon nkan ti a nri loni ti o n sele ngbiyanju lati ya okan wa pelu Jesu ni, bii awon eto kan lori ero-amohun-maworan{TV program},Radio, ati kaseti ti n fi ihoho eniyan han{cassette}, enikan tile so nigbakan pe ko si OLORUN, eyiti Bibeli funrare ti fun ni idahun “asiwere eniyan wipe OLORUN kosi” Psalm 14:1.Ohun wonyi n gbiyanju lati so fun wa pe ko si igbala Okan, kosi si Olorun nibi kankan, nigbati a ba de orun lato maa mo eniti Olorun yio gbala fun ra re. Mo roo jowo mase gba eko odi wonyi gbo rara.Awon miran tile nroo wipe ko si nkan ti o kan wa boya enikan lo sorun apadi tabi orun rere, gege bi omo Olorun eyi gbodo kan wa, lati so fun elomiran nkan ti Olorun n bere lowo re.Ki a yera fun nkan ti ara eni- nikan “Nitori gbogbo won ni n toju nkan ti ara won, ki ise nkan ti ise ti Jesu Kristi” Filippi 2:21.Ki se gbogbo wa lo n fe ki elomiran yipada ninu iwa ibi ti o n wu, iwa anikanjopon po lowo awa eniyan{SELFISHNESS}, ti ko ba je bee o ye ki gbogbo wa gbiyanju lati soro Olorun fun enikan tabi opolopo eniyan. Baba dakun ru wa soke lati ronu- piwada ese wa lai ka ipo tabi ola si nkankan. Looto o le maa so pe, se bi tele nko sin Olorun kankan ti mo si de ipo to ga julo nibi ise mi tabi nibi okun owo mi tabi ninu ilu ti mo wa tabi ninu ile eko mi ati beebee lo, bayi e wa nso fun mi pe Olorun kan wa nibikan. Je kin so fun o pe ‘emi alabosi to gun,ti kosi setan lati ronupiwada ojo iya re lo n sun siwaju’ gbo ohun ti bibeli wi “emi n yo nisisiyi,ki ise nitori ti a mu inu yin baje, sugbon nitori ti a mu inu yin baje si ironupiwada; nitoriti a mu yin baje bi eni iwabi-Olorun, ki eyin ki o mase tipase wa padanu li ohunkohun” 2 Korinti 7:9. Loni a maa nwasu gidi gan nipa nkan ti ara ju nkan ti Olorun lo; bii iwasu ona lati di oloro ojiji, igbati elomiran lo si ilu oyinbo tabi ki a gberawa kale bi eniti o n se ise iyanu fun eniyan,enikan tile sope ohun ni oludasile iwasu ona lati di OLORO. Ko tile woopo loni ki iwasu wa duro lori IGBALA - OKAN igbala okan yi lati odo Olorun ni eyi ti n wa kin se nkan ti eniyan le fun eniyan bii tire, ipa eyiti o kan wa nibe ni lati so oro Olorun ti oye kooro funun lati jeki o mo pe gbogbo eniyan ti a bi nipa ibasepo okunrin ati obinrin elese ni, nipa bayi nko a nilo OLUGBALA ti yio gba wa la kuro ninu ese wa gbogbo. Ju gbogo re lo jeki okan re gba ebun OLORUN sinu aye re, jeki ero re da lori nkan ti n se ti OLORUN ju ti ara lo, korira ese ati awon iwa ibi miran, ki o si feran omo enikeji re gege bi ara re , mase tesiwaju ati maa dese sii “awon kan wipe ti won ba da ese daadaa ti Oorun ba fe se idajo yio ri wipe ese won ti poju yio wa fi ibinu ju won sonu nipa bayi nko? awon yio bo sibe iye dipo kiwon wo inu ina orun apadi , mo eyi daju loni pe, eniyan lo rorun fun daadaa lati gbe ebi fun alare tabi ki o sa sise [mistake] sugbon OLORUN ti mo gbagbo kole sa sise rara, nitori idi eyi nko? pa iru ero bee re lokan re ki o gba JESU lolugbala re”, Feran oro Olorun lati maa ka, Feran Kristi gege bi o ti feran re.
Ni ipari OLORUN alafia yio wa pelu gbogbo yin bi e ti nka iwe yi loo{AMIN}.
Fun alaye sii, ibere, amoran, ebe adura,Eri- Yin, tabi E n fe iwe yi sii, kowe si :-
ReviveThe Whole World For Christ.
P.O.Box 1736,
Osogbo, Osun State. Nigeria.
TI OLORUN BA FI SI O LO KAN LATI RAN ILE-ISE IWE YI LOWO SEE LONI OLA LEE PE JU, KOSI IYE OWO TI O KERE JU LATI FI SILE TABI TI O POJU, KI ORO OLORUN LE MAA GBINLE SII.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment